Ezra 5:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“A bèèrè lọ́wọ́ àwọn àgbààgbà wọn pé, ta ló fun wọn láṣẹ láti tún tẹmpili yìí kọ́ ati láti dá àwọn nǹkan inú rẹ̀ pada sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awa bi awọn àgba wọnni li ère, a si wi fun wọn bayi pe, Tani fun nyin li aṣẹ lati kọ́ ile yi, ati lati mọ odi yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A bi àwọn àgbààgbà, a sì fi ọ̀rọ̀ wá wọn lẹ́nu wò pé, “Ta ni ó fún un yín ní àṣẹ láti tún ilé OLÚWA yìí kọ́ àti láti tún odi rẹ̀ mọ?”