Ezra 6:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Kí Ọlọrun, tí ó yan Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ibi ìsìn rẹ̀, pa ẹni náà run, kì báà ṣe ọba tabi orílẹ̀-èdè kan ni ó bá tàpá sí òfin yìí, tí ó sì ń wá ọ̀nà láti wó ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu. Èmi Dariusi ọba ni mo pa àṣẹ yìí, ẹ sì gbọdọ̀ mú un ṣẹ fínnífínní.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki Ọlọrun ẹniti o mu ki orukọ rẹ̀ ma gbe ibẹ, ki o pa gbogbo ọba, ati orilẹ-ède run, ti yio da ọwọ wọn le lati ṣe ayipada, ati lati pa ile Ọlọrun yi run, ti o wà ni Jerusalemu. Emi Dariusi li o ti paṣẹ, ki a mu u ṣẹ li aijafara.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí Ọlọ́run, tí ó ti jẹ́ kí orúkọ rẹ̀ máa gbé ibẹ̀, kí ó pa gbogbo ọba àti orílẹ̀ èdè rún tí ó bá gbé ọwọ́ sókè láti yí àṣẹ yìí padà tàbí láti wó tẹ́ḿpìlì yìí tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù ṣubú. Èmi Dáríúsì n pàṣẹ rẹ̀, jẹ́ kí ó di mímú ṣẹ láì yí ohunkóhun padà.