Ezra 6:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn àgbààgbà Juu ń kọ́ ilé náà, wọ́n sì ń ṣe àṣeyọrí pẹlu ìdálọ́kànle tí àsọtẹ́lẹ̀ tí wolii Hagai ati Sakaraya, ọmọ Ido ń fún wọn. Wọ́n parí kíkọ́ tẹmpili náà bí Ọlọrun Israẹli ti pa á láṣẹ fún wọn ati gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Kirusi, ati ti Dariusi ati ti Atasasesi, àwọn ọba Pasia.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn àgba Juda si kọle, nwọn si ṣe rere nipa iyanju Haggai woli ati Sekariah ọmọ Iddo. Nwọn si kọle, nwọn si pari rẹ̀ gẹgẹ bi aṣẹ Ọlọrun Israeli, ati gẹgẹ bi aṣẹ Kirusi, ati Dariusi ati Artasasta ọba Persia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn àgbààgbà Júù tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì ń gbèrú sí i lábẹ́ ìwàásù wòlíì Hágáì àti wòlíì Ṣekaráyà, ìran Ídò. Wọ́n parí kíkọ́ ilé OLÚWA gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run Ísírẹ́lì àti àwọn àṣẹ Ṣáírúsì, Dáríúsì àti Aritaṣéṣéṣì àwọn ọba Páṣíà pọ̀.