Ezra 6:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi ya ara wọn sí mímọ́ lápapọ̀, fún ayẹyẹ náà. Wọ́n pa ọ̀dọ́ aguntan Àjọ Ìrékọjá fún àwọn tí wọ́n pada dé láti oko ẹrú, wọ́n pa fún àwọn alufaa ẹlẹgbẹ́ wọn, ati fún àwọn tìkara wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi ti wẹ̀ ara wọn mọ́ bi ẹnikan, gbogbo wọn li o si mọ́, nwọn si pa ẹran irekọja fun gbogbo awọn ọmọ igbekun, ati fun awọn arakunrin wọn, awọn alufa, ati fun awọn tikara wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn àlùfáà àti àwọn ará Léfì ti ya ara wọn sí mímọ́, wọ́n sì jẹ́ mímọ́. Àwọn ará Léfì pa ọ̀dọ́ àgùntàn ti àjọ ìrékọjá fún gbogbo àwọn tí a kó ní ìgbèkùn, fún àwọn àlùfáà arákùnrin wọn àti fún ara wọn.