Ezra 6:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Gbogbo àwọn Juu tí wọ́n pada láti oko ẹrú ati àwọn tí wọ́n kọ ẹ̀sìn ìbọ̀rìṣà sílẹ̀ láti sin OLUWA Ọlọrun Israẹli, tí wọn ń bá wọn gbé ní ilẹ̀ náà, tí wọ́n sì wá síbi ayẹyẹ náà pẹlu wọn, ni wọ́n jọ jẹ àsè náà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn ọmọ Israeli ti o ti inu igbekun pada bọ̀, ati gbogbo iru awọn ti o ti ya ara wọn si ọdọ wọn kuro ninu ẽri awọn keferi ilẹ na, lati ma ṣe afẹri Oluwa Ọlọrun Israeli, si jẹ àse irekọja.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí ó ti dé láti ìgbèkùn jẹ ẹ́ lápapọ̀ pẹ̀lú gbogbo àwọn tí ó ti ya ara wọn kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ àìmọ́ ti àwọn kèfèrí aládùúgbò wọn láti wá OLÚWA Ọlọ́run Ísírẹ́lì.