Ezra 6:22 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ọjọ́ meje ni wọ́n fi fi tayọ̀tayọ̀ ṣe ayẹyẹ Àjọ Àìwúkàrà, nítorí pé Ọlọrun ti fún wọn ní ayọ̀ nítorí inú ọba Asiria tí ó yọ́ sí wọn, tí ó sì ràn wọ́n lọ́wọ́ láti tún ilé Ọlọrun Israẹli kọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si fi ayọ̀ ṣe ajọ aiwukara li ọjọ meje: nitoriti Oluwa ti mu wọn yọ̀, nitoriti o yi ọkàn ọba Assiria pada si ọdọ wọn, lati mu ọwọ wọn le ninu iṣẹ ile Ọlọrun, Ọlọrun Israeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Fún ọjọ́ méje, wọ́n ṣe ayẹyẹ Búrẹ́dì tí kò ní Yíìsìtì pẹ̀lú àjẹtì àkàrà. Nítorí tí OLÚWA ti kún wọn pẹ̀lú ayọ̀ nípa yíyí ọkàn ọba Ásíríà padà, tí ó fi ràn wọ́n lọ́wọ́ lórí iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, Ọlọ́run Ísírẹ́lì.