Ezra 6:3 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ní ọdún kinni ìjọba Kirusi ni ó pàṣẹ pé kí wọn tún ilé Ọlọrun tí ó wà ní Jerusalẹmu kọ́ fún ìrúbọ ati fún ọrẹ ẹbọ sísun. Gíga ilé Ọlọrun náà gbọdọ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27), kí ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ọgọta igbọnwọ, (mita 27).
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọdun ikini Kirusi ọba, Kirusi ọba na paṣẹ nipasẹ ile Ọlọrun ni Jerusalemu pe, Ki a kọ́ ile na, ibi ti nwọn o ma ru ẹbọ, ki a si fi ipilẹ rẹ̀ lelẹ ṣinṣin, ki giga rẹ̀ jẹ́ ọgọta igbọnwọ, ati ibu rẹ̀, ọgọta igbọnwọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọdún kìn-ín-ní ìjọba ọba Ṣáírúsì, ọba pa àṣẹ kan nípa tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run ní Jérúsálẹ́mù: Jẹ́ kí a tún tẹ́ḿpìlì ibi tí a ti ń rú onírúurú ẹbọ kọ́, kí a fi ìpìlẹ̀ rẹ̀ lélẹ̀ ní gíga àti àádọ́rùn-ún (90) ẹsẹ̀ bàtà ní fífẹ̀,