Ezra 6:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Gbogbo ohun èlò ìṣúra wúrà ati fadaka inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, tí Nebukadinesari kó lọ sí Babiloni, ni kí wọ́n kó pada wá sí Jerusalẹmu, kí wọ́n sì fi wọ́n sí ààyè wọn ninu ilé Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu ki a si kó ohun èlo wura ati ti fàdaka ile Ọlọrun pada, ti Nebukadnessari ti kó lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu jade, ti o si ti ko wá si Babiloni, ki a si ko wọn pada, ki a si mu wọn lọ si inu tempili ti o wà ni Jerusalemu, olukuluku ni ipò rẹ̀, ki a si tò wọn si inu ile Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì jẹ́ kí wúrà àti àwọn ohun èlò fàdákà ti ilé Ọlọ́run, tí Nebukadinésárì kó láti ilé OLÚWA ní Jérúsálẹ́mù tí ó sì kó lọ sí Bábílónì, di dídá padà sí àyè wọn nínú tẹ́ḿpìlì ní Jérúsálẹ́mù; kí a kó wọn sí inú ilé Ọlọ́run.