Ezra 6:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ati pé, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe láti ran àwọn àgbààgbà Juu lọ́wọ́ láti kọ́ ilé Ọlọrun náà pé: Ninu àpò ìṣúra ọba ati lára owó bodè ni kí ẹ ti mú, kí ẹ fi san gbogbo owó àwọn òṣìṣẹ́ ní àsanpé, kí iṣẹ́ lè máa lọ láìsí ìdádúró.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu mo paṣẹ li ohun ti ẹnyin o ṣe fun awọn àgba Juda wọnyi, fun kikọ ile Ọlọrun yi: pe, ninu ẹru ọba, li ara owo-odè li oke-odò, ni ki a mã ṣe ináwo fun awọn enia wọnyi li aijafara, ki a máṣe da wọn duro.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síwájú sí i, mo pàṣẹ ohun tí ẹ gbọdọ̀ ṣe fún àwọn àgbààgbà Júù wọ̀nyí lórí kíkọ́ ilé Ọlọ́run yìí: Gbogbo ìnáwó àwọn ọkùnrin yìí ni kí ẹ san lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ lára ìṣúra ti ọba, láti ibi àkójọpọ̀ owó ìlú ti agbègbè Yúfúrátè kí iṣẹ́ náà má bà dúró.