Ezra 6:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Lojoojumọ, ni kí ẹ máa fún àwọn alufaa tí wọ́n wà ní Jerusalẹmu ní iye akọ mààlúù, àgbò, aguntan pẹlu ìwọ̀n ọkà, iyọ̀, ọtí waini ati òróró olifi, tí wọn bá bèèrè fún ẹbọ sísun sí Ọlọrun ọ̀run.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati eyiti nwọn kò le ṣe alaini ẹgbọrọ akọmalu, ati àgbo, pẹlu ọdọ-agutan fun ẹbọ sisun si Ọlọrun ọrun, alikama, iyọ, ọti-waini pẹlu ororo, gẹgẹ bi ilana awọn alufa ti o wà ni Jerusalemu, ki a mu fun wọn li ojojumọ laiyẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohunkóhun tí wọ́n bá fẹ́—àwọn akọ ọ̀dọ́ màlúù, àwọn àgbò, ọ̀dọ́ àgùntàn fún ọrẹ sísun sí Ọlọ́run ọ̀run, àti jéró, iyọ̀, wáìnì àti òróró, ìfiyàn bí àwọn àlùfáà ní Jérúsálẹ́mù ti béèrè ni ẹ gbọdọ̀ fún wọn lójoojúmọ́ láì yẹ̀.