Ezra 7:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Mo pàṣẹ jákèjádò ìjọba mi pé bí ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli tabi àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi bá fẹ́ bá ọ pada lọ sí Jerusalẹmu, kí ó máa bá ọ lọ;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo paṣẹ pe, ki gbogbo enia ninu awọn enia Israeli, ati ninu awọn alufa rẹ̀ ati awọn ọmọ Lefi, ninu ijọba mi, ẹniti o ba fẹ nipa ifẹ inu ara wọn lati gòkẹ lọ si Jerusalemu, ki nwọn ma ba ọ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo pàṣẹ pé ẹnikẹ́ni nínú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà àti àwọn Léfì, ti ó wà ní abẹ́ ìṣàkòóso ìjọba mi, tí ó bá fẹ́ láti bá ọ lọ sí Jérúsálẹ́mù lè tẹ̀lé ọ lọ.