Ezra 7:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
nítorí pé èmi ati àwọn olùdámọ̀ràn mi meje ni a rán ọ lọ láti ṣe ìwádìí fínnífínní lórí Juda ati Jerusalẹmu, gẹ́gẹ́ bí òfin Ọlọrun rẹ tí ó wà lọ́wọ́ rẹ,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Niwọn bi a ti rán ọ lọ lati iwaju ọba lọ ati ti awọn ìgbimọ rẹ̀ mejeje, lati wadi ọ̀ran ti Juda ati Jerusalemu gẹgẹ bi ofin Ọlọrun rẹ ti mbẹ li ọwọ rẹ;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọba àti àwọn ìgbìmọ̀ rẹ̀ méjèèjè rán ọ lọ láti wádìí nípa òfin Ọlọ́run rẹ tí ó wà ní ọwọ́ rẹ nípa Júdà àti Jérúsálẹ́mù.