Ezra 7:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
O níláti kó gbogbo wúrà ati fadaka tí o bá rí ní gbogbo agbègbè Babiloni, ati ọrẹ àtinúwá tí àwọn ọmọ Israẹli ati àwọn alufaa bá fínnúfẹ́dọ̀ dá jọ fún Tẹmpili Ọlọrun wọn ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati gbogbo fàdaka ati wura ti iwọ le ri ni gbogbo igberiko Babiloni, pẹlu ọrẹ atinuwa awọn enia, ati ti awọn alufa, ti iṣe ọrẹ atinuwa fun ile Ọlọrun wọn ti o wà ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
pẹ̀lú gbogbo fàdákà àti wúrà tí ìwọ lè rí ní agbègbè ìjọba Bábílónì àti àwọn ọrẹ àtinúwá àwọn ènìyàn àti ti àwọn àlùfáà fún tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run wọn ní Jérúsálẹ́mù.