Ezra 7:17 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ṣíṣọ́ ni kí o ṣọ́ owó yìí ná: fi ra akọ mààlúù, àgbò, ati ọ̀dọ́ aguntan ati èròjà ẹbọ ohun jíjẹ ati ohun mímu, kí o fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ Tẹmpili Ọlọrun rẹ tí ó wà ní Jerusalẹmu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki iwọ ki o le fi owo yi rà li aijafara, akọmalu, àgbo, ọdọ-agutan, ati ọrẹ ohun jijẹ wọn ati ọrẹ ohun mimu wọn, ki o si fi wọn rubọ li ori pẹpẹ ile Ọlọrun nyin ti o wà ni Jerusalemu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Pẹ̀lú owó yìí, rí i dájú pé ó ra àwọn akọ màlúù, àwọn àgbò àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn, pẹ̀lú ọrẹ ohun jíjẹ (ọkà), àti ọrẹ ohun mímu, kí ìwọ kí ó fi wọ́n rúbọ lórí pẹpẹ tẹ́ḿpìlì Ọlọ́run rẹ ní Jérúsálẹ́mù.