Ezra 7:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Èmi Atasasesi ọba pàṣẹ fún àwọn olùtọ́jú ilé ìṣúra ní agbègbè òdìkejì odò láti pèsè gbogbo nǹkan tí Ẹsira, alufaa akọ̀wé òfin Ọlọrun ọ̀run, bá fẹ́ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati emi, ani Artasasta ọba paṣẹ fun gbogbo awọn olutọju iṣura, ti o wà li oke odò pe, ohunkohun ti Esra alufa, ti iṣe akọwe ofin Ọlọrun ọrun yio bère lọwọ nyin, ki a ṣe e li aijafara,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi, ọba Aritaṣéṣéṣì, pàṣẹ fún gbogbo olùtọ́jú ilé ìṣúra agbègbè Yúfúrátè láìrójú láti pèṣè ohunkóhun tí àlùfáà Ẹ́sírà, olùkọ́ni ní òfin Ọlọ́run ọ̀run bá béèrè lọ́wọ́ yín