Ezra 7:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
A tún fi ń ye yín pé kò bá òfin mu láti gba owó ìṣákọ́lẹ̀, tabi owó bodè, tabi owó orí lọ́wọ́ àwọn alufaa, tabi àwọn ọmọ Lefi, tabi àwọn akọrin, tabi àwọn aṣọ́nà, tabi àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tabi àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn ninu ilé Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu ki ẹnyin ki o mọ̀ dajudaju pe, ẹnyin kò ni oyè lati di owo-ori, owo-odè, ati owo-bodè ru gbogbo awọn alufa, ati awọn ọmọ Lefi, awọn akọrin, awọn adèna, awọn Netinimu, ati awọn iranṣẹ ninu ile Ọlọrun yi,
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ sì ní láti mọ̀ pé ìwọ kò ní àṣẹ láti sọ sisán owó orí, owó òde tàbí owó bodè di dandan fún àwọn àlùfáà, àwọn Léfì, àwọn akọrin, àwọn aṣọ́nà, àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì tàbí àwọn òṣìṣẹ́ mìíràn nínú ilé Ọlọ́run yìí.