Ezra 7:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Kí ìwọ Ẹsira, lo ọgbọ́n tí Ọlọrun rẹ fún ọ, kí o yan àwọn alákòóso ati àwọn adájọ́ tí wọ́n mọ òfin Ọlọrun rẹ, kí wọ́n lè máa ṣe ìdájọ́ àwọn tí wọ́n wà ní agbègbè òdìkejì odò. Kí o sì kọ́ àwọn tí kò mọ òfin Ọlọrun rẹ kí àwọn náà lè mọ̀ ọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati iwọ, Esra, gẹgẹ bi ọgbọ́n Ọlọrun rẹ ti o wà li ọwọ rẹ, yan awọn oloyè ati onidajọ, ti nwọn o ma da ẹjọ fun gbogbo awọn enia ti o wà li oke-odò, gbogbo iru awọn ti o mọ̀ ofin Ọlọrun rẹ, ki ẹnyin ki o si ma kọ́ awọn ti kò mọ̀ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ Ẹ́sírà, ní ìbámu pẹ̀lú ọgbọ́n Ọlọ́run rẹ̀, èyí tí ó ní, yan àwọn adájọ́ àgbà àti àwọn onídàájọ́ láti máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ènìyàn agbègbè—Yúfúrátè—gbogbo àwọn tí ó mọ òfin Ọlọ́run rẹ. Ìwọ yóò sì kọ́ ẹnikẹ́ni tí kò mọ̀ àwọn òfin náà.