Ezra 7:28 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí ó fi ìfẹ́ rẹ̀ tí kì í yẹ̀ hàn mí níwájú ọba, pẹlu àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ pataki pataki. Nítorí pé OLUWA Ọlọrun wà pẹlu mi, mo ṣe ọkàn gírí, mo kó àwọn aṣiwaju àwọn ọmọ Israẹli jọ, mo ní kí wọ́n bá mi kálọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti o si nàwọ anu si mi niwaju ọba ati awọn ìgbimọ rẹ̀, ati niwaju gbogbo awọn alagbara ijoye ọba: mo si ri iranlọwọ gbà gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun mi ti o wà lara mi, mo si ko awọn olori awọn enia jọ lati inu Israeli jade, lati ba mi goke lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹni tí ó jẹ́ kí ojú rere rẹ̀ tàn kàn mí níwájú ọba àti àwọn olùbádámọ̀ràn àti ní iwájú àwọn alágbára ìjòyè ọba. Nítorí ọwọ́ OLÚWA Ọlọ́run wà lára mi, mo mú ọkàn le, mo sì kó àwọn olórí jọ láàrin àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì láti gòkè lọ pẹ̀lú mi.