Ezra 7:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti Babiloni ni Ẹsira tí à ń wí yìí ti dé. Akọ̀wé ni, ó sì já fáfá ninu òfin Mose, tí OLUWA Ọlọrun Israẹli fún wọn. Ọba fún un ní gbogbo nǹkan tí ó bèèrè, nítorí pé ó rí ojurere OLUWA Ọlọrun rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Esra yi li o gòke lati Babiloni wá; o si jẹ ayáwọ́-akọwe ninu ofin Mose, ti Oluwa Ọlọrun Israeli fi fun ni: ọba si fun u li ohun gbogbo ti o bère, gẹgẹ bi ọwọ Oluwa Ọlọrun rẹ̀ ti wà lara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ́sírà yìí gòkè wá láti Bábílónì. Olùkọ́ tí ó ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa òfìn Mósè, èyí tí OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ti fi fún wọn. Ọba sì fi gbogbo ohun tí ó béèrè fún un, nítorí ọwọ́ OLÚWA Ọlọ́run wà lára rẹ̀.