Ezra 8:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo pe gbogbo wọn jọ síbi odò tí ń ṣàn lọ sí Ahafa, a sì pàgọ́ sibẹ fún ọjọ́ mẹta. Nígbà tí mo wo ààrin àwọn eniyan ati àwọn alufaa, n kò rí ọmọ Lefi kankan níbẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si kó wọn jọ pọ li eti odò ti o ṣàn si Ahafa; nibẹ li a si gbe inu agọ li ọjọ mẹta: mo si wò awọn enia rere pẹlu awọn alufa, emi kò si ri ẹnikan ninu awọn ọmọ Lefi nibẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi kó wọn jọ pọ̀ si etí odò ti ń ṣàn lọ sí Áháfà, a pàgọ́ síbẹ̀ fùn odidi ọjọ́ mẹ́ta, nígbà ti mo wo àárin àwọn ènìyàn àti àárin àwọn àlùfáà, ń kò ri ọmọ Léfì kankan níbẹ̀.