Ezra 8:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo rán wọn lọ sọ́dọ̀ Ido, olórí àwọn eniyan ní Kasifia; mo ní kí wọ́n sọ fún Ido ati àwọn arakunrin rẹ̀ tí ń ṣiṣẹ́ ninu tẹmpili pé kí wọ́n fi àwọn eniyan tí yóo máa ṣe iṣẹ́ ìsìn ninu ilé Ọlọrun wa ranṣẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si rán wọn ti awọn ti aṣẹ si ọdọ Iddo, olori ni ibi Kasifia, mo si kọ́ wọn li ohun ti nwọn o wi fun Iddo, ati fun awọn arakunrin rẹ̀, awọn Netinimu ni ibi Kasifia, ki nwọn ki o mu awọn iranṣẹ wá si ọdọ wa fun ile Ọlọrun wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
mo rán wọn sí Ídò, tí ó wà ní ibi ti a ń pè ni Kásífíà, mo sì sọ ohun ti wọn yóò sọ fun Ídò àti àwọn arakunrin rẹ̀ ti wọn jẹ́ òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì ní Kásífíà fún wọn, pé, kí wọn mú àwọn ìránṣẹ́ wá fún wa fún ilé Ọlọ́run wa.