Ezra 8:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Pẹlu ìrànlọ́wọ́ Ọlọrun, wọ́n fi Ṣerebaya, ọlọ́gbọ́n eniyan kan ranṣẹ sí wa. Ọmọ Israẹli ni, láti inú àwọn ọmọ Mahili, ninu ẹ̀yà Lefi: wọ́n fi ranṣẹ pẹlu àwọn ọmọ ati àwọn arakunrin rẹ̀. Gbogbo wọn jẹ́ mejidinlogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati nipa ọwọ rere Ọlọrun wa lara wa, nwọn mu ọkunrin oloye kan fun wa wá, ninu awọn ọmọ Mali, ọmọ Lefi, ọmọ Israeli; ati Ṣerebiah, pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, mejidilogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ọwọ́ àánú Ọlọ́run wa wà lára wa, wọ́n sì mú Ṣérébáyà wá fún wa, ẹni tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ìran Máhílì ọmọ Léfì, ọmọ Ísírẹ́lì, àti àwọn ọmọ Ṣérébáyà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, wọ́n jẹ́ ọkùnrin méjìlélógún (18).