Ezra 8:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
láì tíì ka igba ó lé ogún (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹmpili, tí Dafidi ati àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ láti máa ran àwọn ọmọ Lefi lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a kọ orúkọ wọn sinu ìwé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu awọn Netinimu pẹlu, ti Dafidi ati awọn ijoye ti fi fun isin awọn ọmọ Lefi, ogunlugba Netinimu gbogbo wọn li a kọ orukọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì tún mú ọ̀kànlénígba (220) àwọn òṣìṣẹ́ tẹ́ḿpìlì wá-àwọn ènìyàn tí Dáfídì àti àwọn ìjòyè rẹ gbé kalẹ̀ láti ràn àwọn ọmọ Léfì lọ́wọ́. Gbogbo wọn ni a ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.