Ezra 8:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo sọ fún wọn pé, “A yà yín ati gbogbo nǹkan wọnyi sí mímọ́ fún OLUWA. Fadaka ati wúrà jẹ́ ọrẹ àtinúwá fún OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Mo si wi fun wọn pe, Mimọ́ li ẹnyin si Oluwa; mimọ́ si li ohun èlo wọnyi; ọrẹ atinuwa si Oluwa Ọlọrun awọn baba nyin ni fàdaka ati wura na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin àti àwọn ohum èlò wọ̀nyí ni a ti yà sí mímọ́ fún OLÚWA. Sílífà àti wúrà sì jẹ́ ọrẹ àtinúwá sí OLÚWA Ọlọ́run àwọn baba yín.