Ezra 8:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ máa tọ́jú wọn kí ẹ sì máa pa wọ́n mọ́ títí tí ẹ óo fi wọ̀n wọ́n níwájú àwọn olórí alufaa, àwọn ọmọ Lefi ati àwọn baálé baálé Israẹli ní Jerusalẹmu ninu yàrá ilé OLUWA.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ ma tọju wọn, ki ẹ si ma pa wọn mọ, titi ẹnyin o fi wọ̀n wọn niwaju awọn olori ninu awọn alufa ati ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori ninu awọn baba Israeli ni Jerusalemu, ninu iyàrá ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tọ́jú wọn dáradára títí ìwọ yóò se fi òṣùwọ̀n wọ̀n wọ́n jáde kúrò ni ilé OLÚWA ni Jérúsálẹ́mù ní iwájú àwọn aṣáájú àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì àti ní iwájú olórí ìdílé gbogbo ni Ísírẹ́lì.”