Ezra 8:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kejila oṣù kinni ni a kúrò ní odò Ahafa à ń bọ̀ wá sí Jerusalẹmu. Ọlọrun wà pẹlu wa, ó dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá ati àwọn dánàdánà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awa lọ kuro ni odò Ahafa, li ọjọ ekejila oṣu ikini, lati lọ si Jerusalemu: ọwọ Ọlọrun wa si wà lara wa, o si gba wa lọwọ awọn ọta, ati lọwọ iru awọn ti o ba ni ibuba li ọ̀na.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kejìlá oṣù kìn-ín-ní ni a gbéra kúrò ní ẹ̀bá odò Áháfà láti lọ sí Jérúsálẹ́mù. Ọwọ́ Ọlọ́run wa wà lára wa, ó sì dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀ta àti àwọn adigunjalè ní ọ̀nà wa.