Ezra 8:33 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ní ọjọ́ kẹrin, a gbéra, a lọ sí ilé Ọlọrun, a wọn fadaka, wúrà ati àwọn ohun èlò, a sì kó wọn lé Meremoti, alufaa, ọmọ Uraya lọ́wọ́. Àwọn tí wọ́n wà pẹlu rẹ̀ níbẹ̀ ni Eleasari, ọmọ Finehasi, pẹlu àwọn ọmọ Lefi, Josabadi, ọmọ Jeṣua, ati Noadaya, ọmọ Binui.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Li ọjọ ẹkẹrin li a wọ̀n fàdaka ati wura ati ohun-èlo wọnni ninu ile Ọlọrun wa si ọwọ Meremoti ọmọ Uriah, alufa, ati pẹlu rẹ̀ ni Eleasari ọmọ Finehasi; ati pẹlu wọn ni Josabadi ọmọ Jeṣua, ati Noadia, ọmọ Binnui, awọn ọmọ Lefi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní ọjọ́ kẹrin, a wọn ohun èlò fàdákà àti wúrà àti àwọn ohun èlò mímọ lé àlùfáà Mérémótì ọmọ Úráyà lọ́wọ́, láti inú ilé Ọlọ́run wa, Élíásérì ọmọ Fínéhásì wà pẹ̀lú rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Léfì Jósábádì ọmọ Jésíúà àti Núádáyà ọmọ Bínúì wà níbẹ̀ pẹ̀lú.