Ezra 8:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé fi akọ mààlúù mejila rú ọrẹ ẹbọ sísun sí Ọlọrun Israẹli fún ẹ̀yà Israẹli mejila, pẹlu àgbò mẹrindinlọgọrun-un, ọ̀dọ́ aguntan mẹtadinlọgọrun-un, ati òbúkọ mejila fún ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀ṣẹ̀. Gbogbo àwọn ẹran wọnyi jẹ́ ẹbọ sísun fún Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọmọ awọn ti a ti ko lọ, awọn ti o ti inu igbekùn pada bọ̀, ru ẹbọ sisun si Ọlọrun Israeli, ẹgbọrọ malu mejila, àgbo mẹrindilọgọrun, ọdọ-agutan mẹtadilọgọrin, ati obukọ mejila fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: gbogbo eyi jẹ ẹbọ sisun si Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni àwọn ìgbèkùn tí o ti pada láti ilẹ̀ àjèjì rú ẹbọ ọrẹ sísun sí Ọlọ́run Ísírẹ́lì: akọ màlúù méjìlá fún gbogbo Ísírẹ́lì, àádọ́rùn-ún-o-lé-mẹ́ta akọ ọdọ àgùntàn àti òbúkọ méjìlá fún ọrẹ sísun sí OLÚWA.