Ezra 9:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn nǹkan wọnyi, àwọn olórí àwọn ọmọ Israẹli wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n ní: “Àwọn ọmọ Israẹli pẹlu àwọn alufaa ati àwọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò ninu ìwà ìríra àwọn ará Kenaani ati àwọn ará Hiti, ti àwọn ará Perisi ati àwọn ará Jebusi, ti àwọn ará Amoni ati àwọn ará Moabu, àwọn ará Ijipti, ati àwọn ará Amori.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI a si ti ṣe nkan wọnyi tan, awọn ijoye wá si ọdọ mi, wipe, Awọn enia Israeli, ati awọn alufa, pẹlu awọn ọmọ Lefi kò ya ara wọn si ọ̀tọ kuro ninu awọn enia ilẹ wọnni, gẹgẹ bi irira wọn, ti awọn ara Kenaani, awọn ara Hitti, awọn ara Perisi, awọn ara Jebusi, awọn ara Ammoni, awọn ara Moabu, awọn ara Egipti, ati ti awọn ara Amori.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lẹ́yìn ìgbà tí a ti ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tán, àwọn olórí tọ̀ mí wá wọ́n sì wí pé, Àwọn ènìyàn Ísírẹ́lì, ti ó fi mọ́ àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, kò tì í ya ara wọn sọ́tọ̀ kúrò láàrin àwọn ènìyàn agbègbè tí wọ́n ń ṣe ohun ìríra bí i ti àwọn ọmọ Kénánì, Hítì, Pérísì, Jébúsì, Ámónì, Móábù Éjíbítì àti Ámórì.