Ezra 9:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àní, òfin tí o ṣe, tí o fi rán àwọn wolii sí wa pé, ilẹ̀ tí ẹ̀ ń lọ gbà yìí jẹ́ ilẹ̀ tí ó kún fún ẹ̀gbin ati ohun ìríra, pẹlu ìwà ẹ̀gbin àwọn eniyan jákèjádò ilẹ̀ náà ti sọ ọ́ di aláìmọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti iwọ ti pa lati ẹnu awọn woli iranṣẹ rẹ wá, wipe, Ilẹ na ti ẹnyin nlọ igbà nì, ilẹ alaimọ́ ni, fun ẹgbin awọn enia ilẹ na, fun irira wọn, pẹlu ìwa-ẽri ti nwọn fi kun lati ikangun kan de ekeji.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
èyí tí ìwọ fún wa láti ipaṣẹ̀ àwọn wòlíì ìrànṣẹ rẹ, nígbà ti ìwọ wí pé ilẹ̀ ti ẹ̀yin ń wọ̀ lọ láti lọ gbà jẹ́ ilẹ̀ tí ó di àìmọ̀ pẹ̀lú ìwà ìbàjẹ́ àwọn ènìyàn rẹ, nípa ṣíṣe ohun ìríra ilẹ̀ náà ti kún fún ohun àìmọ́ láti igun kan dé ìkejì.