Ezra 9:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, ẹ má fi àwọn ọmọbinrin yín fún àwọn ọmọkunrin wọn, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ fẹ́ àwọn ọmọbinrin wọn fún àwọn ọmọkunrin yín. Ẹ kò gbọdọ̀ wá ire wọn tabi alaafia, kí ẹ lè lágbára, kí ẹ lè jẹ èrè ilẹ̀ náà, kí ó sì lè jẹ́ ohun ìní fún àwọn ìran yín títí lae.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nitorina ki ẹnyin ki o máṣe fi ọmọ nyin obinrin fun ọmọ wọn ọkunrin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe mu ọmọ wọn obinrin fun ọmọ nyin ọkunrin, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o máṣe wá alafia wọn tabi irọra wọn titi lai: ki ẹnyin ki o le ni agbara, ki ẹ si le ma jẹ ire ilẹ na, ki ẹ si le fi i silẹ fun awọn ọmọ nyin ni ini titi lai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, ẹ má ṣe fi àwọn ọmọbìnrin yín fún àwọn ọmọkùnrin wọn ní ìyàwó tàbí kí ẹ fẹ́ àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin yín ní ìyàwó. Ẹ má ṣe dá májẹ̀mú àlàáfíà pẹ̀lú wọn nígbà-kí-gbà kí ẹ̀yin kí ó sì le lágbára, kí ẹ sì jẹ ohun dáradára ilẹ̀ náà, kí ẹ sì fi sílẹ̀ fún àwọn ọmọ yín gẹ́gẹ́ bí ogún ayé rayé;