Ezra 9:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí wa, nítorí ìwà burúkú wa ati ẹ̀ṣẹ̀ ńlá tí a dá, a rí i pé ìyà tí ìwọ Ọlọrun fi jẹ wá kéré sí ẹ̀ṣẹ̀ wa; o jẹ́ kí àwa tí a pọ̀ tó báyìí ṣẹ́kù sílẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati lẹhin gbogbo eyi ti o de si wa nitori iṣe buburu wa, ati nitori ẹbi wa nla, nitoripe iwọ Ọlọrun wa ti dá wa si ju bi o ti yẹ lọ fun aiṣedede wa, o si fi iru igbala bi eyi fun wa;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ohun tí ó ti sẹlẹ̀ sí wa jẹ́ ayọrísí iṣẹ́ búburú wa àti ẹ̀bi-ẹ̀ṣẹ̀ ńlá wa, ṣíbẹ̀, Ọlọ́run wa, ìjìyà ti ìwọ fún wa kéré si ìjìyà tí ó yẹ fún ẹ̀ṣẹ̀ ti a dá, ìwọ sì fún wa ní àwọn ènìyàn tó sẹ́kù bí èyí.