Ezra 9:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ǹjẹ́ àwa tí a ṣẹ́kù yìí tún gbọdọ̀ máa rú òfin rẹ, kí á máa fẹ́ aya láàrin àwọn orílẹ̀-èdè tí wọn ń ṣe ohun ìríra? Ǹjẹ́ o kò ní bínú sí wa tóbẹ́ẹ̀ tí o óo fi pa wá run, tí a kò fi ní ṣẹ́ku ẹyọ ẹnìkan mọ́ tabi kí ẹyọ ẹnìkan sá àsálà?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awa iba ha tun ru ofin rẹ? ki awa ki o si ma ba awọn enia irira wọnyi dá ana? iwọ kì o ha binu si wa titi iwọ o fi pa wa run tan, tobẹ̃ ti ẹnikan kò si ni kù, tabi ẹnikan ti o sala?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwa tún yẹ̀ kúrò nínú àṣẹ rẹ, kí a sì máa ṣe ìgbéyàwó papọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn tí wọn ti ṣe onírúurú ohun ìríra báyìí? Ṣe ìwọ kò ní bínú sí wa láti pa wá run tí kì yóò sẹ́ ku ẹnìkẹ́ni tí yóò là?