Ezra 9:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA Ọlọrun Israẹli, olódodo ni ọ́, nítorí díẹ̀ ninu wa ṣẹ́kù tí a sá àsálà títí di òní yìí. A wà níwájú rẹ báyìí pẹlu ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ẹni tí ó lè dúró níwájú rẹ báyìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Olododo ni iwọ Oluwa Ọlọrun Israeli: awa ni iyokù ati asala gẹgẹ bi o ti ri li oni yi: wò o, awa duro niwaju rẹ ninu ẹbi wa, nitoripe awa ki o le duro niwaju rẹ nitori eyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìwọ OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì, ìwọ jẹ́ olódodo O dá wa sí lónìí bí àwọn tí ó ṣẹ́kà. Àwa nìyí níwájú rẹ nínú ẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀ wa, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé nítorí rẹ̀ ẹyọ ẹnìkan kò lè dúró níwájú rẹ.