Ezra 9:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n ń fẹ́ ọmọ lọ́wọ́ wọn fún ara wọn ati fún àwọn ọmọ wọn; àwọn ẹ̀yà mímọ́ sì ti darapọ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí ó yí wọn ká. Àwọn tí wọ́n jẹ̀bi ọ̀rọ̀ náà jù ni àwọn olórí ati àwọn eniyan pataki ní Israẹli.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe nwọn mu awọn ọmọ wọn obinrin fun aya wọn, ati fun awọn ọmọ wọn ọkunrin: tobẹ̃ ti a da iru-ọmọ mimọ́ pọ̀ mọ awọn enia ilẹ wọnni: ọwọ awọn ijoye, ati awọn olori si ni pataki ninu irekọja yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ti fẹ́ lára àwọn ọmọbìnrin wọn fún ara wọn àti fún àwọn ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí aya, wọ́n ti da ìran mímọ́ pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn ti ó wà ní àyíká wọn. Àwọn olórí àti àwọn ìjòyè ta àwọn ènìyàn tó kù yọ nínú hihu ìwà “Àìsòótọ́.”