Ezra 9:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo jókòó bẹ́ẹ̀ títí di àkókò ẹbọ àṣáálẹ́. Gbogbo àwọn tí wọ́n bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọrun rọ̀gbà yí mi ká nítorí aiṣootọ àwọn tí wọ́n ti oko ẹrú dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni olukuluku awọn ti o warìri si ọ̀rọ Ọlọrun Israeli ko ara wọn jọ si ọdọ mi, nitori irekọja awọn wọnni ti a ti ko lọ; mo si joko ni ijaya titi di igba ẹbọ aṣalẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni gbogbo àwọn tí ó bẹ̀rù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ísírẹ́lì kó ara wọn jọ yí mi ká nítorí àìsòótọ́ àwọn ìgbékùn yìí. Èmi sì jókòó níbẹ̀ ní ìbànújẹ́ títí di àkókò ìrúbọ àṣálẹ̀.