Ezra 9:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Láti ayé àwọn baba wa títí di ìsinsìnyìí, ni àwa eniyan rẹ ti ń dẹ́ṣẹ̀ lọpọlọpọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwọn ọba ati àwọn alufaa wa ti bọ́ sọ́wọ́ àwọn ọba ilẹ̀ àjèjì; wọ́n pa wá, wọ́n dè wá ní ìgbèkùn, wọ́n sì kó wa lẹ́rù. A wá di ẹni ẹ̀gàn títí di òní.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lati ọjọ awọn baba wa li awa ti wà ninu ẹbi nla titi di oni; ati nitori ẹ̀ṣẹ wa li a fi awa, awọn ọba wa, ati awọn alufa wa, le awọn ọba ilẹ wọnni lọwọ fun idà, fun igbèkun, ati fun ikogun, ati fun idamu oju, gẹgẹ bi o ti ri li oni oloni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Láti ìgbà àwọn baba wá, títí di ìsinsin yìí, àìṣedéédéé wa ti pọ̀ jọjọ. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wa, àwa àti àwọn ọba wa àti àwọn àlùfáà wa ni a ti sọ di ẹni idà àti ìgbèkùn, ìkógun àti ẹni ẹ̀ṣín lọ́wọ́ àwọn àjèjì ọba, bí ó ti rí lónìí.