Ezra 9:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ṣugbọn fún ìgbà díẹ̀ ní àkókò yìí, OLUWA Ọlọrun wa, o ṣàánú wa, o dá díẹ̀ sí ninu wa, à ń gbé ní àìléwu ní ibi mímọ́ rẹ. O jẹ́ kí ara dẹ̀ wá díẹ̀ ní oko ẹrú, o sì ń mú inú wa dùn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi fun igba diẹ, li a si fi ore-ọfẹ fun wa lati ọdọ Oluwa Ọlọrun wa wá lati salà, ati lati fi ẽkàn fun wa ni ibi mimọ́ rẹ̀, ki Ọlọrun wa ki o le mu oju wa mọlẹ, ki o si tun wa gbe dide diẹ ninu oko-ẹrú wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ni ìsinsin yìí, fún ìgbà díẹ̀, OLÚWA Ọlọ́run ti fi àánú rẹ̀ dá àwa tí ó sẹ́kù sí tí ó sì fún wa ni ibi pàtàkì nínú ibi mímọ́ rẹ̀, nítorí náà Ọlọ́run wa ti fi ìmọ́lẹ̀ fún ojú wa àti ìgbé ayé túntún kúrò nínú ìgbékùn wa.