Galatians 2:14 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí mo rí i pé ohun tí wọn ń ṣe kò bá òtítọ́ ìyìn rere mu, mo wí fún Peteru níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ tí ó jẹ́ Juu bá ti ń ṣe bí àwọn yòókù, tí o kò ṣe bí àṣà àwọn Juu, kí ló dé tí o fi fẹ́ kí àwọn tí kì í ṣe Juu ṣe ara wọn bíi Juu?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nigbati mo ri pe nwọn kò rìn dẽdẽ gẹgẹ bi otitọ ihinrere, mo wi fun Peteru niwaju gbogbo wọn pe, Bi iwọ, ti iṣe Ju, ba nrìn gẹgẹ bi ìwa awọn Keferi, laiṣe bi awọn Ju, ẽṣe ti iwọ fi nfi agbara mu awọn Keferi lati mã rìn bi awọn Ju?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí mo rí i pé wọn kò rìn déédéé gẹ́gẹ́ bí òtítọ́ ìyìn rere, mo wí fún Pétérù níwájú gbogbo wọn pé, “Bí ìwọ, tí ì ṣe Júù ba ń rìn gẹ́gẹ́ bí ìwà àwọn aláìkọlà, è é ṣe tí ìwọ fi ń fi agbára mu àwọn aláìkọlà láti máa rìn bí àwọn Júù?