Galatians 2:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
mọ̀ pé kò sí ẹnikẹ́ni tí Ọlọrun yóo dá láre nípa iṣẹ́ òfin, àfi nípa igbagbọ ninu Jesu Kristi. Àwa pàápàá gba Kristi Jesu gbọ́, kí Ọlọrun lè dá wa láre nípa igbagbọ ninu rẹ̀, kì í ṣe nípa iṣẹ́ òfin.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti a mọ̀ pe a ko da ẹnikẹni lare nipa iṣẹ ofin, bikoṣe nipa igbagbọ́ ninu Jesu Kristi, ani awa na gbà Jesu Kristi gbọ́, ki a ba le da wa lare nipa igbagbọ́ ti Kristi, kì si iṣe nipa iṣẹ ofin: nitoripe nipa iṣẹ ofin kò si enia kan ti a o dalare.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tí a mọ̀ pé a kò dá ẹnikẹni láre nípa iṣẹ́ òfin, bí kò ṣe nípa ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kírísítì, àní àwa pẹ̀lú gbà Jésù Kírísítì gbọ́, kí a báa lè dá wa láre nípa ìgbàgbọ́ tí Kírísítì, kì í sì i ṣe nípa iṣẹ́ òfin: nítorí pé nípa iṣẹ́ òfin kò sí ènìyàn kan tí a ó dá láre.