Galatians 2:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo wà láàyè, ṣugbọn kì í ṣe èmi ni mo wà láàyè; Kristi ni ó ń gbé inú mi. Ìgbé-ayé tí mò ń gbé ninu ara nisinsinyii, nípa igbagbọ ninu Ọmọ Ọlọrun tí ó fẹ́ràn mi ni. Ó fẹ́ràn mi tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A ti kàn mi mọ agbelebu pẹlu Kristi: ṣugbọn mo wà lãye, sibẹ ki iṣe emi mọ́, ṣugbọn Kristi wà lãye ninu mi: wiwà ti mo si wà lãye ninu ara, mo wa lãye ninu igbagbọ Ọmọ Ọlọrun, ẹniti o fẹ mi, ti o si fi on tikararẹ̀ fun mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
A ti kàn mí mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú Kírísítì, èmí kò sì wà láàyè mó, ṣùgbọ́n Kírísítì ń gbé inú mi wíwà tí mo sì wà láàyè nínú ara, mo wà láàyè nínú ìgbàgbọ́ ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí o fẹ́ mi, tí ó sì fi òun tìkararẹ̀ fún mi.