Galatians 3:16 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí Ọlọrun ṣe ìlérí fún Abrahamu ati irú-ọmọ rẹ̀, kì í ṣe ọ̀rọ̀ gbogbo irú-ọmọ rẹ̀ ni Ọlọrun ń sọ, ṣugbọn ọmọ kanṣoṣo ni ó tọ́ka sí. Ó sọ pé, “Ati fún irú-ọmọ rẹ.” Ọmọ náà ni Kristi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ fun Abrahamu ati fun irú-ọmọ rẹ̀ li a ti ṣe awọn ileri na. On kò wipe, Fun awọn irú ọmọ, bi ẹnipe ọ̀pọlọpọ; ṣugbọn bi ẹnipe ọ̀kan, ati fun irú-ọmọ rẹ, eyiti iṣe Kristi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ fún Ábúráhámù àti fún irú ọmọ rẹ̀ ni a ti ṣe àwọn ìlérí náà. Òun kò ṣe wí pé, “Àti fún irú-ọmọ rẹ̀,” èyí tí í ṣe Kírísítì.