Galatians 3:8 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀ pé nípa igbagbọ ni Ọlọrun yóo fi dá àwọn tí kì í ṣe Juu láre, ó waasu ìyìn rere fún Abrahamu pé, “Gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu yóo di ẹni ibukun nípasẹ̀ rẹ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi iwe-mimọ́ si ti ri i tẹlẹ pe, Ọlọrun yio dá awọn Keferi lare nipa igbagbọ́, o ti wasu ihinrere ṣaju fun Abrahamu, o nwipe, Ninu rẹ li a o bukún fun gbogbo orilẹ-ède.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ìwé-mímọ́ sì tí wí tẹ́lẹ̀ pé, Ọlọ́run yóò dá aláìkọlà láre nípa ìgbàgbọ́, ó tí wàásù ìyìn rere ṣáájú fún Ábúráhámù, ó ń wí pé, “Nínú rẹ̀ ni a ó bùkún fún gbogbo orílẹ̀-èdè.”