Galatians 4:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, “Máa yọ̀, ìwọ àgàn tí kò bímọ rí. Sọ̀rọ̀ kí o kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí. Nítorí àwọn ọmọ àgàn pọ̀ ju ti obinrin tí ó ní ọkọ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori a ti kọ ọ pe, Mã yọ̀, iwọ àgan ti kò bímọ: bú si ayọ̀ ki o si kigbe soke, iwọ ti kò rọbi rí; nitori awọn ọmọ ẹni alahoro pọ̀ jù ti abilekọ lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí a ti kọ ọ́ pé, “Má a yọ̀, ìwọ obìnrin àgàn tí kò bímọ, bú sí ayọ̀ kí o sì kígbe sókè, ìwọ tí kò rọbí rí; nítorí àwọn ọmọ obìnrin náà tí a kọ̀sílẹ̀ yóò pọ̀ ju ti obìnrin tó ní ọkọ lọ.”