Galatians 6:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn ní tèmi, kí á má rí i pé mò ń fọ́nnu kiri àfi nítorí agbelebu Oluwa wa Jesu Kristi, nípasẹ̀ ẹni tí ayé yìí ti di ohun tí a kàn mọ́ agbelebu lójú mi, tí èmi náà sì di ẹni tí a kàn mọ́ agbelebu lójú rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn ki a máṣe ri pe emi nṣogo, bikoṣe ninu agbelebu Jesu Kristi Oluwa wa, nipasẹ ẹniti a ti kàn aiye mọ agbelebu fun mi, ati emi fun aiye.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n kí a má ṣe rí i pé èmi ń ṣògo, bí kò ṣe nínú àgbélébùú Jésù Kírísítì Olúwa wa, nípaṣẹ̀ ẹni tí a ti kan ayé mọ́ àgbélébùú fún mi, àti èmi fún ayé.