Genesis 1:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọlọrun pàṣẹ pé kí àwọn ìmọ́lẹ̀ wà ní ojú ọ̀run, láti fi ààlà sí ààrin ọ̀sán ati òru, kí wọ́n wà láti jẹ́ àmì, ati láti máa fi àkókò àjọ̀dún, ọjọ́, ati ọdún hàn,
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọlọrun si wipe, Ki awọn imọlẹ ki o wà li ofurufu ọrun, lati pàla ọsán on oru; ki nwọn ki o si ma wà fun àmi, ati fun akoko, ati fun ọjọ́, ati fun ọdún:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ọlọ́run sì wí pé “Jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ kí ó wà ní ojú ọ̀run, làti pààlà sí àárin ọ̀sán àti òru, kí wọn ó sì máa wà fún àmì láti mọ àwọn àsìkò, àti àwọn ọjọ́ àti àwọn ọdún,