Genesis 10:25 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ọmọkunrin meji ni Eberi bí, orúkọ ekinni ni Pelegi, nítorí pé ní ìgbà tirẹ̀ ni ayé pínyà, orúkọ ekeji ni Jokitani.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ati fun Eberi li a bí ọmọkunrin meji; orukọ ekini ni Pelegi; nitori nigba ọjọ́ rẹ̀ ni ilẹ yà; orukọ arakunrin rẹ̀ ni Joktani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ébérì sì bí ọmọ méjì: ọ̀kan sì ń jẹ́ Pélégì, nítorí ní ìgbà ayé rẹ̀ ni ilẹ̀ ayé pín sí oríṣìíríṣìí ẹ̀yà àti èdè. Orúkọ arákùnrin rẹ̀ ni Jókítanì.