Genesis 11:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Tẹra mú Abramu ọmọ rẹ̀, ati Lọti, ọmọ Harani tíí ṣe ọmọ Tẹra, ati Sarai aya Abramu, ó kó gbogbo wọn jáde kúrò ní Uri ti ilẹ̀ Kalidea, wọ́n ń lọ sí ilẹ̀ Kenaani. Ṣugbọn nígbà tí wọ́n dé Harani, wọ́n tẹ̀dó sibẹ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Tera si mu Abramu ọmọ rẹ̀, ati Loti, ọmọ Harani, ọmọ ọmọ rẹ̀, ati Sarai aya ọmọ rẹ̀, aya Abramu ọmọ rẹ̀; nwọn si ba wọn jade kuro ni Uri ti Kaldea, lati lọ si ilẹ Kenaani; nwọn si wá titi de Harani, nwọn si joko sibẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Tẹ́rà sì mú ọmọ rẹ̀ Ábúrámù àti Lọ́tì ọmọ Áránì, ọmọ-ọmọ rẹ̀, ó sì mú Sáráì tí i ṣe aya ọmọ rẹ̀. Ábúrámù pẹ̀lú, gbogbo wọn sì jáde kúrò ní Úrì ti Kálídéà láti lọ sí ilẹ̀ Kénánì. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọn dé Áránì wọ́n tẹ̀dó síbẹ̀.