Genesis 11:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìdí nìyí tí wọ́n ṣe pe orúkọ ìlú náà ní Babeli, nítorí níbẹ̀ ni OLUWA ti da èdè gbogbo ayé rú, láti ibẹ̀ ni ó sì ti fọ́n wọn káàkiri gbogbo orílẹ̀ ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina li a ṣe npè orukọ ilu na ni Babeli; nitori ibẹ̀ li OLUWA gbe dà ède araiye rú, lati ibẹ̀ lọ OLUWA si tú wọn ká kiri si ori ilẹ gbogbo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ìdí èyí ni a fi pè é ní Bábílónì nítorí ní ibẹ̀ ni Ọlọ́run ti da èdè gbogbo ayé rú, tí ó sì tú àwọn ènìyàn ká sí gbogbo orí ilẹ̀ ayé.