Genesis 12:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà náà ni OLUWA fara han Abramu, ó wí pé, “Àwọn ọmọ ati ọmọ ọmọ rẹ ni n óo fi ilẹ̀ yìí fún.” Abramu bá tẹ́ pẹpẹ kan níbẹ̀ fún OLUWA tí ó fara hàn án.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sì farahan Ábúrámù, ó sì wí fún un pé, “Ìran rẹ ni Èmi yóò fi ilẹ̀ yìí fún.” Ábúrámù tẹ́ pẹpẹ kan ṣíbẹ̀ fún OLÚWA tí ó fara hàn-án.